Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ti ko din ni mejidinlọgọjọ (158) ni awọn ṣe idanwo fun, ti wọn gba fọọmu lati jade du ipo aṣofin.
Ipo aṣofin mẹrinlelogun la gbọ pe o wa nile igbimọ aṣofin naa, ti wọn yoo ṣoju ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa kaakiri ipinlẹ Kwara.
Nigba to n sọrọ lọjọ Aje, ọsẹ yii, alaga igbimọ ayẹwo awọn oludije naa, Ọjọgbọn Success Musa jẹ ko di mimọ pe eto idibo awa-ara-wa yoo waye lẹgbẹ naa lai ṣe ojusaaju.
Ọjọgbọn Musa fidi rẹ mulẹ pe pupọ awọn araalu ni wọn pe awọn oludije naa lati gba fọọmu, ki wọn le ṣoju wọn.
"Mo gbọ pe awọn oludije mejidinlọgọjọ ni wọn ti gba fọọmu sipo aṣofin nikan. Eyi safihan eto oṣelu awa-ara-wa. Ohun ti APC duro fun ree. O si jẹ igbesẹ adari ti alaga ato gomina gun le," Ọjọgbọn Musa sọ bẹẹ.
No comments:
Post a Comment