Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara ti kede ọkan lara awọn oludije to n lewaju ninu eto idibo sile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Akewejẹ Olayinka Fafoluyi gẹgẹ bii pe o ti jawe olubori ninu ilana eto ayẹwo to waye
Ninu atẹjade idupẹ to fi sita laipẹ yii, Akewejẹ jẹ ko di mimọ pe aṣeyọri toun ṣe nivi eto ayẹwo to waye naa, kii ṣe nipa irin-ajo oun nikan, bi ko ṣe nipa ifọwọsowọpọ ati agbajọ lati mu agbegbe Irepodun lagbara, ko si wa ni iṣọkan, ati pe oun fi ara jin lati sin awọn eeyan kọja awọn ileri toun ṣe, eyi to pe ni Service Beyond Promises.
O wa gbe oriyin fun gbogbo awọn adije ti wọn kopa ninu ayẹwo naa fun ọkan akin ti wọn ni, ati pe eto oṣelu awa-ara-wa maa n ṣe daadaa nigba ti eeyan ba fi ara re jin fun iṣẹ idagbasoke ilu ati agbegbe.
“Mo bọwọ fun awọn adije to kopa nibi ayẹwo to waye, mo si dupẹ lọwọ wọn,” o sọ bẹẹ.
O wa rọ gbogbo adije lati fi ara jin fun ẹgbẹ, ki wọn si duro ṣinṣin ninu iṣọkan ati aṣeyọri bi eto idibo ọdun 2027 ṣe n sunmọ.
“Gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ to farajin, asiko ree fun iṣọkan, ibọwọ funra ẹni, ati afarajin fun aṣeyọri ẹgbẹ wa.
“Aṣẹ ẹgbẹ gbọdọ jẹ ilana ti a maa tẹle, nitori pe ni igbẹyin, aṣeyọri APC ni aṣeyọri gbogbo wa patapata, ati fun awọn ti a yan sipo lati ṣiṣẹ.
“Ni apapọ, ka le jọ tẹsiwaju nipa agbara", Akewejẹ sọ bẹẹ.
No comments:
Post a Comment