Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ileeṣẹ Adron Homes lati kopa nibi eto ayẹyẹ Ọdun Ọlọjọ to maa n waye niluu Ile-Ifẹ, ipinlẹ Ọṣun.
Ayẹyẹ Ọdun Ọlọjọ ti yoo waye lọdun 2026 ti a wa yii, ni yoo jẹ igba kọianla iru rẹ, latigba ti wọn ti bẹrẹ.
Ọpọ awọn ileeṣẹ nla-nla ni wọn maa n kopa nibẹ nipasẹ ṣiṣe agbatẹru eto ibilẹ naa, paapaa lati fi ṣe igbelarugẹ fun eto ọrọ aje wọn.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, nibi ayẹyẹ ti ọdun yii Adron Homes yoo ti ṣe afihan awọn ọgba ile igbalode wọn ti wọn pe ni Premium Estate, ti wọn ṣẹṣẹ gbe kalẹ niluu Ile-Ifẹ.
Yatọ si awọn ileeṣẹ nla-nla ti yoo kopa nibi eto naa, ọpọ awọn ọba alaye kaakiri ipinlẹ Ọṣun ati agbaye ni yoo wa nibẹ.
Lasiko ipade awọn akọroyin to ṣaaju eto ti ọdun yii ti wọn pe akori rẹ ni "Didaabo bo aṣa nipasẹ irin ajo afẹ to duro ṣinṣin" (“Culture Preservation Through Sustainable Tourism.”)
Ahead of the festival, Adron Homes made a strong appearance at the press conference and unveiling of the 2026 edition with a delegation comprising key members of its Western operations.
Awọn alẹnulọrọ ati akọṣẹmọṣẹ kaakiri ẹka ileeṣẹ naa ẹkun Ila-Oorun ni Adron Homes ti gbe dide lati kopa.
Awọn naa ni: Ogundapo Odunola, igbakeji alakoso agba ni ẹka Western Super-Cluster; Johnson Olugbenga, igbakeji alakoso ni ẹka Western Galaxy 1; ati Shobowale Taiwo, igbakeji alakoso ni ẹka ipolowo ọja, ti Livingspring World.
Seyi Oyekunle ti Adenike Ajobo yoo maa ṣoju fun, ni yoo maa sọrọ nipa ileeṣẹ naa ati awọn afojusun wọn.

No comments:
Post a Comment