Ko si igbesẹ lati fi owo kun owo ina mọnamọna - Ijọba apapọ pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 22, 2026

Ko si igbesẹ lati fi owo kun owo ina mọnamọna - Ijọba apapọ pariwo sita


Ijọba apapọ ilẹ Naijiria ti sọ pe ki awọn araalu lọ fi ọkan wọn balẹ, nitori pe ko si igbesẹ to n lọ lati fi owo kun owo ti awọn eeyan n ra ina mọnamọna.

Minisita fọrọ ina mọnamọna, Joseph Tegbe lo sọ bẹẹ lọjọ Aje, ọsẹ yii niluu Abuja, nibi ipade awọn akọroyin to pe, lati fi saami ayẹyẹ ọgọrun ọjọ to gba ipo naa.

Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii ni Tegbe gba ipo naa, lẹyin ti Minisita tẹlẹ, Adebayo Adelabu kọwe fi ipo naa silẹ.

Tegbe sọ pe oniruuru ipe ori aago loun ti gba lopin ọsẹ to kọja nipa wi pe ijọba apapọ n ṣagbeyẹwo lati ṣe afikun lori owo ina mọnamọna.

Minisita naa sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ, ati pe awọn oloṣelu ni wọn n gbe iroyin naa kaakiri lati fi ṣi awọn araalu lọkan, fun eto idibo ọdun 2027 ti wọn n foju wọna fun.

O ni afojusun ijọba apapọ ni lati pese ina mọnamọna to ja geere fun gbogbo ọmọ Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI