Ileeṣẹ eleto aabo ara-ẹni-laabo ilu ti a mọ si Sifu Difẹnsi nilẹ Naijiria ti fi oju ọga agba ileeṣẹ naa, ẹka ti ipinlẹ Niger han f'awọn akọroyin, lori ẹsun aṣemaṣe.
Ipinlẹ Niger ni awọn Sifu Difẹnsi ti mu awọn afurasi awakusa to le ni ọgọta lọsẹ to kọja, ti wọn si ju wọn si atimọle.
Lasiko ti wọn sọ pe iwadii n lọ lọwọ, ni a gbọ pe awọn mẹtadinlọgbọn ninu awọn afurasi ọhun ti ku sinu ahamọ wọn.
Iku awọn eeyan naa la gbọ pe o mu ifura dani, nitori bi wọn ṣe sọ pe kii ṣoju lasan.
Lara awọn afurasi to sọrọ jẹ ko ye awọn eeyan pe ipo ti ahamọ naa wa, ko dara rara fun awọn eeyan lati lo wakati mẹrinlelogun.
Bo tilẹ pe ohun ti awọn kan n sọ ni pe niṣe ni wọn fin wọn ni afẹfẹ kan ti ko ba ilera mu, eyi to jẹ ki ọpọ ninu wọn ku.
Ṣugbọn ni bayii, ileeṣẹ Sifu Difẹnsi nilẹ Naijiria i wa foju ọga agba nipinlẹ Niger, Siyaka Aniviye ati awọn mẹtalelogun miran han fawọn akọroyin.
Sifu Difẹnsi sọ pe gbogbo wọn ni yoo foju ba ile-ẹjọ lati sọ ohun ti wọn mọ nipa iku awọn mẹtadinlọgbọn naa.
Ọga agba fun Sifu Difẹnsi nilẹ Naijiria, Ọjọgbọn Ahmed Abubakar Audi ti ṣèlérí wi pe idajọ ododo yoo waye lori iṣẹlẹ naa, ati pe iku awọn alaiṣẹ naa ko nii lọ lasan.
Awọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi tọwọ tẹ naa ni Subaru Siyaka Aniviye to jẹ ọga ni ipinlẹ Niger; DCC Ajayi Philips, alakoso ẹka iwadii; DCC John Agrahau Chagwa, alakoso ẹka amuṣẹṣe; DCC Obafemi Elvis; ACC Stephen Tsado; CSC Oluwadare Sunday; CSC Annas Shittu Lamino; SC Usman Isah Ndamaka; ati DSC Aminu Sule Garba.
Awọn yooku ni: DSC Musa Marafa; DSC Isah Sulaiman; ASCI Hassan Muhammad; ASCI Alhassan Muhammad; Aliyu Sallah, on guard duty; IC Abdullahi Sale; IC Mohammed N. Sonfada; Mohammed Jiya; Sale Adamu; Haruna Muhammed; CCA Baba Muhamma; CAI Isah Sanusi; CAI Liman Abubakar; CAI Bala Usman; ati CAI Ahmed Wushishi.

No comments:
Post a Comment