Ẹgbẹ awọn oniroyin ni ede abinibi, League of Yoruba Media Practitioners (LYMP), ti ki gbajumọ oloṣelu ati olori pataki nilu Ẹgba, Ọdọfin Ṣẹgun Ṣowunmi, ku oriire lori iyansipo rẹ sinu igbimọ ipolongo aarẹ ti ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) ṣe atunṣe rẹ.
Ṣowunmi wa lara awọn eekan igbimọ naa to ma mojuto ẹka ikansaraalu ati iroyin , eyi to ma kopa ribiribi ninu ipolongo atunyansipo Aarẹ Bọla Tinubu.
Lara awọn olokiki miran ti orukọ wọn wa ninu atojọ tuntun naa ni Minisita fun Olu Ilu ilẹ wa l'Abuja, Nyesom Wike, ati Gomina Ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke.
Wike ni yoo ṣe alabojuto ipolongo aarẹ ni Ipinlẹ Rivers ati Olu Ilẹ wa l'Abuja , nigba ti Adeleke yoo ṣe alabojuto ipolongo naa ni Ipinlẹ Ọṣun.
Awọn miran to wa ninu ẹka ibanisọrọ ati iroyin ni Minisita fun Ọkọ Ofurufu, Festus Keyamo; Abdulmumin Jibrin; ati Lere Ọlayinka, to jẹ oluranlọwọ fun Wike lori ọrọ iroyin. Bakan naa ni wọn tun yan Ọbafẹmi George gẹgẹ bi oluranlọwọ lori ọrọ iroyin.
Igbimọ na jẹ akojọpọ awọn gomina, awọn aṣofin, awọn minisita, awọn olori ẹgbẹ oṣelu ati awọn alẹnulọrọ lẹka eto ọrọ aje ti wọn si ma ṣiṣẹpọ fun atunyansipo Aarẹ Tinubu .
Sẹnetọ Abdulaziz Yari ni Oludari Agba igbimọ ipolongo naa, nigba ti Sẹnetọ Adams Oshiomhole yoo jẹ igbakeji rẹ nigbati Fẹmi Gbajabiamila yoo ma bojuto ikorajọpọ awọn olufẹ ati alatilẹyin aarẹ. Gomina Ipinlẹ Imo, Hope Uzodimma, yoo tẹsiwaju gẹgẹ bi akọwe igbimọ naa.
LYMP ninu ọrọ ikinni ku oriire naa sọ pe iyansipo Ṣẹgun Ṣowunmi jẹ anfaani lati kopa ninu iṣẹ ikansaraalu, ibanisọrọ ati ipolongo oṣelu ni orileede Naijiria.
No comments:
Post a Comment