Ajọ to n ṣagbeyẹwo ohun jijẹ ati mimu nilẹ Naijiria, National Agency for Food and Drug Administration and Control, NAFDAC, ti sọ pe ohun ti ba ọpọlọpọ ayederu oogun jẹ nipinlẹ Rivers.
NAFDAC sọ pe ọpọ ayederu oogun, tomato igbalode inu ọra ati kẹmika to le ni biliọnu meji ataabọ (N2.6b) lohun ba jẹ, nitori pe ọjọ ti lọ lori wọn.
Awọn alakoso ajọ naa sọ pe awọn ọja wọnyi lo jẹ awọn eyi ti NAFDAC fofin gba, ati awọn eyi tawọn ileeṣẹ to n ṣe wọn jade mọ-ọn-mọ ko wa fun awọn.
Igbesẹ naa lo waye nile idalẹsi ti ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ didanu nipinlẹ naa, RIWAMA, eyi to wa lopopona marosẹ Oyigbo, Elelenwo, Port Harcourt.
Alakoso ajọ NAFDAC ni ẹka iwadii ti fifi ofin mulẹ, Martins Iluyomade, ẹni to ṣoju ọga agba pata Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye, sọ pe ọdun to kọja ni igbesẹ naa bẹrẹ.
Iluyomade sọ pe oun ati ọga ileeṣẹ aṣọbode ni wọn jọ bẹrẹ eto naa, nigba ti ileeṣẹ aṣọbode rọwọ to ọkọ akẹru, ti wọn si fa a le awọn lọwọ.
“Apapọ iye ọja ti a fẹẹ dana sun lonii jẹ biliọnu meji ataabọ le diẹ (N2.6b) naira,” Iluyomade ṣalaye.

No comments:
Post a Comment