Hassan ati Abubakar seku pa ore won l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 6, 2017

Hassan ati Abubakar seku pa ore won l'Abeokuta

Bi kii ba a se pe awon olopaa tete dide lati gbe igbese ni, o seese ki Hassan Amodu ati Abubakar Abdullah ti won fesun kan wi pe won ji Taye Amodu gbe, ti won tun seku pa a, o seese ki won ti rin jinna nitori ki asiri won ma ba a tu sita.

Awon odaran naa
Ohun ta a gbo ni pe daran-daran lawon meteeta, iyen Hassan, Abubakar ati Taye, ati pe ore ni won, sugbon se ni won loro yi pada nigba ti won so pe Hassan ati Abubakar se ilara eniketa won, ti won si pinu lati gbemi e.

Eyi lo fa a ti won fi jii gbe lagbegbe Obada Oko lojo ketalelogun osu to koja, ti won si pa a nipakupa, bee ni won tun ji maalu e mejo gbe salo.

Awon ara agbegbe Obada Oko ti won fura si won ni won loo foro naa to awon olopaa FSARS leti, ti won si gbera lati loo koju won, sugbon iyalenu lo je pe awon eeyan naa ti rin jinna.

AWIKONKO gbo pe nigba ti won maa fi ri won, Imeko lona Orileede Benin lasiri won ti pada tu ni nnkan bii aago marun aabo irole ojo naa.

http://www.awikonko.com.ng/2017/11/eyi-ni-bi-tirela-se-te-seyi-omo-egbe.html 

Inu igbo aginju nla kan ni won so pe won loo tedo sii, nibi ti won ti maa n sise ibi won, nibe ni won ti ri ibon pump action kan ati ota ibon merin gba lowo won.

Agbenuso ileese olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe bi iroyin naa se te Komisana won lowo lo ti pase pe ki oga awon SARS to wa ni Obada Oko rii daju pe won mu awon odaran naa bale, toun naa si pase fawon to wa labe e lati teteb gbera.
Abimbola so pe lesekese towo ti te won ni won ti n ka boroboro pe ki won se awon jeje, ati pe awon ko mon on mo pa, sugbon agidi to n bawon se lasiko tawon n muu lo lo je kawon sesi pa a.

Bee lo so pe bi won se pa Taye tan ni won tun loo sinku e bii ti eran ti ko wulo, tawon si tun ko maalu e mejo salo.

Ni bayii, Ahmed Iliyasu ti wa a seleri wi pe oun ko nii foju aanu wo awon odaran naa, won gbodo foju bale ejo dandan leyin tawon ba ti pari ise iwadii won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI